Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Kol 1:9
Àwọn Ará Kólósè
4 Awọn ọjọ
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú Jésù
Ojọ́ Márùn-din-logun
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!