← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Iṣe Apo 9:17
Bẹ̀rẹ̀ L'ọ́tun
7 ọjọ
Ọdún Tuntun. Ọjọ́ Tuntun. Ọlọ́run ṣ'ẹ̀dá gbogbo ìsípòpadà yìí láti rán wá l'étí pé Òun ni Ọlọ́run Ìbẹ̀rẹ̀ Ohun Tuntun. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fí ọ̀rọ̀ dá ayé, Ó lè s'ọ̀rọ̀ sí òkùnkùn ayé rẹ, kí Ó ṣ'ẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún ọ. Ṣé o kò sàì f'ẹ́ràn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun! Gẹ́gẹ́ bíi ìlànà ẹ̀kọ́ yìí! Máa bá wá kálọ!
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ojo Méjìlá
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!