Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Iṣe Apo 4:19

Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Tí Yíó Yí Ayé Rẹ Padà
Ọjọ́ Mẹ́rìn
KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ayé rẹ rọrùn nípa f'ífojúsí KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN fún gbogbo ọdún. Ìrọ̀rùn tó wà nínú ṣíṣe àwárí ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run ní fún ọ jẹ́ kí ó jẹ́ kóríyá fún ìgbé-ayé ọ̀tọ̀. Wúruwùru àti ìdíjúpọ̀ ma ń ṣe okùnfà ìlọ́ra àti ìdálọ́wọ́kọ́, nígbàtí ìrọ̀rùn àti àfojúsùn a maá yọrí sí àṣeyọrí àti ìjágaara. Ètò-ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yíó fi bí a ti ń la aàrín gbùngbùn àníyàn rẹ kọjá láti ṣe àwárí ìran kìkì ọ̀rọ̀ fún gbogbo ọdún.

Ìgbọ́ràn
2 Ọ̀sẹ̀
Jésù fún rara Rẹ̀ sọ wípé ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn Rẹ̀ yóò gbọ́ràn sí ẹ̀kọ́-o Rẹ̀. Láì bìkítà ohun tí ó ba ná wa, ìgbọ́ràn wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. Ètò yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbọ́ràn: Bí a ṣe lè ṣẹ̀ ìtọ́jú ìṣàrò ìdúróṣinṣin, ipa àánú, bí ìgbọ́ràn ṣe tú wa sílẹ̀ àti bùkún ayé wa, àti diẹ sii.