Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Tim 4:4
![Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John Bevere](/_next/image?url=https%3A%2F%2F%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F4846%2F640x360.jpg&w=1920&q=75)
Pípa Kríptónáìtì Pẹlú John Bevere
Ọjọ́ méje
Gẹ́gẹ́ bíi okùnrin alágbára ní tí à ń pè ní Superman, tí ó lè borí gbogbo ọ̀tá, ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Krístì, ní agbára àt'òkè wá láti borí àwọn ìṣòro tí ó d'ojú kọ ọ́. Wàhálà tí ó wà fún ìwọ àti Superman yìí ni pé, kríptónáìtì ńbẹ tí ó fẹ́ jí agbára yín. Ètò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fa gbogbo kríptónáìtì ẹ̀mí tu kúrò nínú ayé rẹ, kí ó baà lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí Olórun gbé fún ọ, àti kí o lè gbé ayé àìlódiwọ̀n.
![Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!](/_next/image?url=https%3A%2F%2F%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F34240%2F640x360.jpg&w=1920&q=75)
Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!
Ọjọ́ 7
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!