Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Kor 2:9
Mọ Ohùn Ọlọ́run // Kọ́ L'áti Pàdé Rẹ̀
Ọjọ́ Mẹ́rìn
Ohùn Ọlọ́run lè wá bíi ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tàbí ìró ìjì líle. Ohun gbòógì ni l'áti dá a mọ̀, bí ó ti wù kí ó wá—àti kí a gbàgbọ́ wí pé Ó dára, wí pé Ó tóbi ju èyíkéyìí àwọn ìjàkadì wa lọ. Bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí kí o sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síí kọ́ bí a ṣe lè pàdé Rẹ̀, ohùn Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀ —kí o sì da ara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ń ní ìrírí Rush |Ẹ̀mí Mímọ́ Ní Ayé Òde-Òní.
Ìràpadà Ìlépa-Ọkàn
Ọjọ́ Méje
Kíni a lè ṣe nígbà tí àwọn ìlépa wa bá dàbí èyí tó jìnà réré tàbí bíi ìgbà tí a kò bá lè bá a láíláí? Lẹ́yìn tí mo borí ìlòkulò àti ìbanilọ́kànjẹ́, pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀, mo ti dojúkọ ìbéèrè yìí lẹ́ẹ̀kànsi. Bóyá ò ń ní ìpèníjà ti àjálù tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ìbànújẹ́ ti àkókò ìdádúró, ìlépa Ọlọ́run fún ìgbésí-ayé rẹ ṣì wà láàyè! Ọ̀rẹ́, àkókò tó láti lá àlá lẹ́ẹ̀kansi.