LUKU 21
21
Ọrẹ Tí Opó Kan Ṣe
(Mak 12:41-44)
1Bí Jesu ti gbé ojú sókè ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ bí wọ́n ti ń dá owó ọrẹ wọn sinu àpótí ìṣúra. 2Ó wá rí talaka opó kan, tí ó fi kọbọ meji sibẹ. 3Ó ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, owó ọrẹ talaka opó yìí ju ti gbogbo àwọn yòókù lọ. 4Nítorí gbogbo àwọn yòókù mú ọrẹ wá ninu ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ní; ṣugbọn òun tí ó jẹ́ aláìní, ó mú gbogbo ohun tí ó fi ẹ̀mí tẹ̀ wá.”
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé A Óo Wó Tẹmpili
(Mat 24:1-2; Mak 13:1-2)
5Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa Tẹmpili, wọ́n ń sọ nípa àwọn òkúta dáradára tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ati ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Jesu bá dáhùn pé, 6“Ẹ rí gbogbo nǹkan wọnyi, ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí òkúta kan lórí ekeji tí a kò ní wó lulẹ̀.”
Àwọn Àmì Àkókò Náà
(Mat 24:3-14; Mak 13:3-13)
7Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹ. Kí ni yóo sì jẹ́ àmì nígbà tí wọn yóo bá fi ṣẹ?”
8Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí á má ṣe tàn yín jẹ. Nítorí ọ̀pọ̀ yóo wá ní orúkọ mi, tí wọn yóo wí pé, ‘Èmi ni Mesaya’ ati pé, ‘Àkókò náà súnmọ́ tòsí.’ Ẹ má tẹ̀lé wọn. 9Nígbà tí ẹ bá gbúròó ogun ati ìrúkèrúdò, ẹ má jẹ́ kí ó dẹ́rùbà yín. Nítorí dandan ni kí nǹkan wọnyi kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ṣugbọn òpin kò níí tíì dé.”
10Ó tún fi kún un fún wọn pé “Orílẹ̀-èdè kan yóo máa gbógun ti ekeji, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba kan yóo sì máa gbógun ti ekeji. 11Ilẹ̀ yóo mì tìtì. Ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn yóo wà ní ibi gbogbo. Ohun ẹ̀rù ati àwọn àmì ńlá yóo hàn lójú ọ̀run. 12Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi. 13Anfaani ni èyí yóo jẹ́ fun yín láti jẹ́rìí. 14Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín, 15nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín. 16Àwọn òbí yín, ati àwọn arakunrin yín, àwọn ẹbí yín, ati àwọn ọ̀rẹ́ yín, yóo kọ̀ yín, wọn yóo sì pa òmíràn ninu yín. 17Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. 18Ṣugbọn irun orí yín kankan kò ní ṣègbé. 19Ẹ óo gba ọkàn yín là nípa ìdúróṣinṣin yín.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ Pé Ogun Yóo Kó Ìlú Jerusalẹmu
(Mat 24:15-21; Mak 13:14-19)
20“Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí. 21Nígbà náà kí àwọn tí ó bá wà ní Judia sálọ sórí òkè. Kí àwọn tí ó bá wà ninu ìlú sá kúrò níbẹ̀. Kí àwọn tí ó bá wà ninu abúlé má sá wọ inú ìlú lọ. 22Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ. 23Àwọn obinrin tí ó lóyún ati àwọn tí ó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ gbé! Nítorí ìdààmú pupọ yóo wà ní ayé, ibinu Ọlọrun yóo wà lórí àwọn eniyan yìí. 24Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé.
Àkókò Tí Ọmọ-Eniyan Yóo Dé
(Mat 24:29-31; Mak 13:24-27)
25“Àmì yóo yọ ní ojú oòrùn ati ní ojú òṣùpá ati lára àwọn ìràwọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dààmú nígbà tí wọ́n bá gbọ́ tí òkun ń hó, tí ó ń ru sókè. 26Àwọn eniyan yóo kú sára nítorí ìbẹ̀rù, nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run ni a óo mì tìtì. 27Nígbà náà ni wọn óo rí Ọmọ-Eniyan tí óo máa bọ̀ ninu ìkùukùu pẹlu agbára ati ògo ńlá. 28Ẹ jẹ́ kí inú yín kí ó dùn, kí ẹ wá máa yan, nígbà tí gbogbo nǹkan wọnyi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, nítorí àkókò òmìnira yín ni ó súnmọ́ tòsí.”
Ẹ̀kọ́ Tí Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kọ́ni
(Mat 24:32-35; Mak 13:28-31)
29Ó pa òwe kan fún wọn, ó ní, “Ẹ wo igi ọ̀pọ̀tọ́ ati gbogbo igi yòókù. 30Nígbà tí ẹ bá rí i, tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn dé. 31Bẹ́ẹ̀ náà ni, nígbà tí ẹ bá rí i, tí gbogbo nǹkan wọnyi ń ṣẹlẹ̀, ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọrun súnmọ́ tòsí.
32“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí kò ní kọjá lọ kí gbogbo nǹkan wọnyi tó ṣẹ. 33Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.
Ẹ Ṣọ́ra
34“Ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má jẹ́ kí ayẹyẹ, tabi ìfiṣòfò, tabi ọtí mímu, ati àníyàn ayé gba ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé lójijì ni ọjọ́ náà yóo dé ba yín bí ìgbà tí tàkúté bá mú ẹran. 35Nítorí ọjọ́ náà yóo dé bá gbogbo eniyan tí ó wà ní ayé. 36Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura nígbà gbogbo pé, kí ẹ lè lágbára láti borí gbogbo àwọn ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ-Eniyan.”
37Ní ọ̀sán, Jesu a máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili; lálẹ́, á lọ sùn ní orí Òkè Olifi. 38Gbogbo eniyan a máa tètè jí láti lọ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili.#21:38 Ninu àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn, níhìn-ín ni ìtàn obinrin tí a ká mọ́ ṣíṣe àgbèrè wà (Joh 7:53–8:11).
Kasalukuyang Napili:
LUKU 21: YCE
Haylayt
Ibahagi
Kopyahin
Gusto mo bang ma-save ang iyong mga hinaylayt sa lahat ng iyong device? Mag-sign up o mag-sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010