LUKU 19
19
Jesu ati Sakiu
1Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá. 2Ọkunrin kan wà tí ó ń jẹ́ Sakiu. Òun ni olórí agbowó-odè níbẹ̀. Ó sì lówó. 3Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni. 4Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá. 5Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.”
6Ni Sakiu bá sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á lálejò. 7Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!”
8Sakiu bá dìde dúró, ó sọ fún Oluwa pé, “N óo pín ààbọ̀ ohun tí mo ní fún àwọn talaka. Bí mo bá sì ti fi ọ̀nà èrú gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, mo ṣetán láti dá a pada ní ìlọ́po mẹrin.”
9Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà. 10Nítoí Ọmọ-Eniyan dé láti wá àwọn tí wọ́n sọnù kiri, ati láti gbà wọ́n là.”#Mat 18:11
Òwe Nípa Owó Wúrà
(Mat 25:14-30)
11Bí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnyi, ó tún fi òwe kan bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àwọn eniyan sí rò pé ó tó àkókò tí ìjọba Ọlọrun yóo farahàn. 12Nítorí náà ó sọ fún wọn pé, “Ọkunrin ìjòyè pataki kan lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n fẹ́ fi jọba níbẹ̀ kí ó sì pada wálé lẹ́yìn náà 13Ó bá pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní owó wúrà kọ̀ọ̀kan. Ó ní, ‘Ẹ máa lọ fi ṣòwò kí n tó dé.’ 14Ṣugbọn àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ibẹ̀ kórìíra rẹ̀. Wọ́n bá rán ikọ̀ ṣiwaju rẹ̀ láti lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ kí ọkunrin yìí jọba lórí àwọn!
15“Nígbà tí ọkunrin yìí jọba tán, tí ó pada dé, ó bá ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó ti fún lówó, kí ó baà mọ èrè tí wọ́n ti jẹ. 16Ekinni bá dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà kan tí o fún mi pa owó wúrà mẹ́wàá.’ 17Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ọmọ-ọ̀dọ̀ rere. O ti ṣe olóòótọ́ ninu ohun kékeré. Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ 18Ekeji dé, ó ní, ‘Alàgbà, mo ti fi owó wúrà rẹ pa owó wúrà marun-un.’ 19Oluwa rẹ̀ wí fún òun náà pé, ‘Mo fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí ìlú marun-un.’
20“Ẹkẹta dé, ó ní, ‘Alàgbà, owó wúrà rẹ nìyí, aṣọ ni mo fi dì í, mo sì fi pamọ́, 21nítorí mo bẹ̀rù rẹ. Nítorí òǹrorò eniyan ni ọ́. Níbi tí o kò fi nǹkan sí ni o máa ń wá a sí; níbi tí o kò fúnrúgbìn sí ni o ti máa ń kórè.’ 22Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ gan-an ni n óo fi ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ burúkú yìí. O mọ̀ pé níbi tí n kò fi nǹkan sí ni mo máa ń wá a sí, ati pé níbi tí n kò fúnrúgbìn sí ni mo ti máa ń kórè. 23Kí ni kò jẹ́ kí o lọ fi owó mi pamọ́ sí banki, tí ó fi jẹ́ pé bí mo ti dé yìí, ǹ bá gbà á pẹlu èlé?’
24“Ó bá sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó wúrà náà ní ọwọ́ rẹ̀, kí ẹ fún ẹni tí ó ní owó wúrà mẹ́wàá.’ 25Wọ́n bá dá a lóhùn pé, ‘Alàgbà, ṣebí òun ti ní owó wúrà mẹ́wàá!’ 26Ó wá sọ fún wọn pé, ‘Gbogbo ẹni tí ó bá ní ni a óo tún fún sí i. Ọwọ́ ẹni tí kò sì ní, ni a óo ti gba ìba díẹ̀ tí ó ní! 27Ní ti àwọn ọ̀tá mi wọnyi, àwọn tí kò fẹ́ kí n jọba, ẹ mú wọn wá síhìn-ín, kí ẹ pa wọ́n lójú mi!’ ”
28Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 29Nígbà tí ó súnmọ́ ẹ̀bá Bẹtifage ati Bẹtani, ní apá òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi, ó rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tí ó wà ní ọ̀kánkán yìí. Nígbà tí ẹ bá wọ ibẹ̀, ẹ óo rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so mọ́lẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ fà á wá. 31Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ”
32Àwọn tí ó rán bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí ó ti sọ fún wọn. 33Nígbà tí wọn ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn oluwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”
34Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.” 35Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún. 36Bí ó ti ń lọ, wọ́n ń tẹ́ ẹ̀wù wọn sọ́nà.
37Nígbà tí ó súnmọ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Olifi, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ayọ̀ kígbe sókè, wọ́n ń yin Ọlọrun nítorí gbogbo ohun ńlá tí wọ́n ti rí. 38Wọ́n ń wí pé,
“Aláásìkí ni ẹni tí ó ń bọ̀ bí ọba ní orúkọ Oluwa.
Alaafia ní ọ̀run! Ògo ní òkè ọ̀run!”#O. Daf 118:26
39Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ Farisi tí wọ́n wà láàrin àwọn eniyan sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”
Jesu Sunkún Lórí Jerusalẹmu
41Nígbà tí wọ́n súnmọ́ etí ìlú, ó wo ìlú náà, ó bá bú sẹ́kún lórí rẹ̀. 42Ó ní, “Ìbá ti dára tó lónìí, bí o bá mọ̀ lónìí ohun tí ó jẹ́ ọ̀nà alaafia rẹ! Ṣugbọn ó pamọ́ fún ọ. 43Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ọ̀tá rẹ yóo gbógun tì ọ́, wọn óo yí ọ ká, wọn yóo há ọ mọ́ yípo. 44Wọn yóo wó ọ lulẹ̀, wọn yóo sì pa àwọn eniyan tí ó wà ninu rẹ. Wọn kò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ekeji ninu rẹ, nítorí o kò fura nígbà tí Ọlọrun wá bẹ̀ ọ́ wò!”
Jesu Lòdì sí Lílo Tẹmpili Bí Ọjà
(Mat 21:12-17; Mak 11:15-19; Joh 2:13-22)
45Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde. 46Ó sọ fún wọn pè, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!”#Ais 56:7; Jer 7:11
47Ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili lojoojumọ. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin, pẹlu àtìlẹ́yìn àwọn eniyan pataki-pataki ní ìlú, ń wá ọ̀nà láti pa á,#Luk 21:37 48ṣugbọn wọn kò rí ọ̀nà, nítorí gbogbo eniyan ń fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Kasalukuyang Napili:
LUKU 19: YCE
Haylayt
Ibahagi
Kopyahin
Gusto mo bang ma-save ang iyong mga hinaylayt sa lahat ng iyong device? Mag-sign up o mag-sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010