LUKU 16
16
Òwe Ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n Ẹ̀wẹ́
1Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò. 2Ọ̀gá rẹ̀ bá pè é, ó sọ fún un pé, ‘Irú ìròyìn wo ni mò ń gbọ́ nípa rẹ yìí? Ṣírò iṣẹ́ rẹ bí ọmọ-ọ̀dọ̀, nítorí n óo dá ọ dúró lẹ́nu iṣẹ́.’ 3Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o, nítorí ọ̀gá mi yóo dá mi dúró lẹ́nu iṣẹ́. Èmi nìyí, n kò lè roko. Ojú sì ń tì mí láti máa ṣagbe. 4Mo mọ ohun tí n óo ṣe, kí àwọn eniyan lè gbà mí sinu ilé wọn nígbà tí wọ́n bá gba iṣẹ́ lọ́wọ́ mi.’
5“Ó bá pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí ó jẹ ọ̀gá rẹ̀ ní gbèsè. Ó bi ekinni pé, ‘Èló ni o jẹ ọ̀gá mi?’ 6Òun bá dáhùn pé, ‘Ọgọrun-un garawa epo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, tètè jókòó, kọ aadọta.’ 7Ó bi ekeji pé, ‘Ìwọ ńkọ́? Èló ni o jẹ?’ Ó ní, ‘Ẹgbẹrun òṣùnwọ̀n àgbàdo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, kọ ẹgbẹrin.’
8“Ọ̀gá ọmọ-ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ náà yìn ín nítorí pé ó gbọ́n. Nítorí àwọn ọmọ ayé yìí mọ ọ̀nà ọgbọ́n tí wọ́n fi ń bá ara wọn lò ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.
9“Ní tèmi, mò ń sọ fun yín, fún anfaani ara yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí wá ọ̀rẹ́ fún ara yín, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí owó kò bá sí mọ́, kí wọn lè gbà yín sí inú ibùgbé tí yóo wà títí lae. 10Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré yóo ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan ńlá. 11Nítorí náà bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa nǹkan owó ti ayé yìí, ta ni yóo fi dúkìá tòótọ́ sí ìkáwọ́ yín? 12Bí ẹ kò bá ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nípa ohun tí ó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ta ni yóo fun yín ní ohun tí ó jẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín?
13“Kò sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má sì ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún sin owó.”#Mat 6:24
Òfin ati Ìjọba Ọlọrun
(Mat 11:12-13; 5:31-32; Mak 10:11-12)
14Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i. 15Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.
16“Ìwé òfin Mose ati ìwé àwọn wolii ni ó wà fún ìlànà títí di àkókò Johanu. Láti ìgbà náà ni a ti ń waasu ìyìn rere ti ìjọba Ọlọrun. Pẹlu ipá sì ni olukuluku fi ń wọ̀ ọ́.#Mat 11:12-13 17Ó rọrùn kí ọ̀run ati ayé kọjá ju pé kí kínńkínní ninu òfin kí ó má ṣẹ lọ.#Mat 5:18
18“Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀ tí ó gbé iyawo mìíràn ṣe àgbèrè. Bí ẹnìkan bá sì gbé obinrin tí a ti kọ̀ sílẹ̀ ní iyawo òun náà ṣe àgbèrè.#Mat 5:32; 1 Kọr 7:10-11
Ọkunrin Ọlọ́rọ̀ ati Lasaru
19“Ọkunrin kán wà tí ó lówó. Aṣọ àlàárì ati àwọn aṣọ olówó iyebíye mìíràn ni ó máa ń wọ̀. Oúnjẹ àdídùn ni ó máa ń jẹ, lojoojumọ ni ó máa ń se àsè.#Tob 4:9-11 20Talaka kan wà tí ó ń jẹ́ Lasaru, tíí máa ń jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé ọlọ́rọ̀ yìí. Gbogbo ara Lasaru jẹ́ kìkì egbò. 21Inú rẹ̀ ìbá dùn láti máa jẹ ẹ̀rúnrún tí ó ń bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili olówó yìí. Pẹlu bẹ́ẹ̀ náà, ajá a máa wá lá egbò ara rẹ̀.
22“Nígbà tí ó yá, talaka yìí kú, àwọn angẹli bá gbé e lọ sọ́dọ̀ Abrahamu. Olówó náà kú, a sì sin ín. 23Ní ipò òkú ni ó rí ara rẹ̀, tí ó ń joró. Ó wá rí Abrahamu ní òkèèrè pẹlu Lasaru ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. 24Ó bá pè é, ó ní, ‘Abrahamu, Baba, ṣàánú mi. Rán Lasaru kí ó ti ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó wá kán an sí mi láhọ́n, nítorí mò ń jẹ ìrora ninu iná yìí.’
25“Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ, ranti pé nígbà tí o wà láyé, kìkì ohun rere ni o gbà, nígbà tí ó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni Lasaru gbà. Nisinsinyii, ìdẹ̀ra ti dé bá Lasaru nígbà tí ìwọ ń jẹ̀rora. 26Ati pé ọ̀gbun ńlá kan wà láàrin àwa ati ẹ̀yin, tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó bá fẹ́ kọjá sí ọ̀dọ̀ yín kò ní lè kọjá; bákan náà àwọn tí ó bá fẹ́ ti ọ̀hún kọjá wá sí ọ̀dọ̀ wa kò ní lè kọjá.’ 27Olówó náà wá sọ pé, ‘Baba, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀ ọ́, rán Lasaru lọ sí ilé baba mi. 28Arakunrin marun-un ni mo ní; kí ó lọ kìlọ̀ fún wọn kí àwọn náà má baà wá sí ibi oró yìí.’
29“Ṣugbọn Abrahamu dá a lóhùn pé, ‘Wọ́n ní ìwé Mose ati ìwé àwọn wolii. Kí wọ́n fetí sí wọn.’ 30Ṣugbọn ọlọ́rọ̀ náà ní, ‘Ó tì, Abrahamu, Baba! Bí ẹnìkan bá jí dìde ninu òkú, tí ó lọ sọ́dọ̀ wọn, wọn yóo ronupiwada.’ 31Ṣugbọn Abrahamu sọ fún un pé, ‘Bí wọn kò bá fetí sí ohun tí Mose ati àwọn wolii kọ, bí ẹni tí ó ti kú bá tilẹ̀ jí dìde tí ó lọ bá wọn, kò ní lè yí wọn lọ́kàn pada.’ ”
Kasalukuyang Napili:
LUKU 16: YCE
Haylayt
Ibahagi
Kopyahin
Gusto mo bang ma-save ang iyong mga hinaylayt sa lahat ng iyong device? Mag-sign up o mag-sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010