1
LUKU 13:24
Yoruba Bible
“Ẹ dù láti gba ẹnu ọ̀nà tí ó há wọlé, nítorí mò ń sọ fun yín pé ọpọlọpọ ni ó ń wá ọ̀nà láti wọlé ṣugbọn wọn kò lè wọlé.
Paghambingin
I-explore LUKU 13:24
2
LUKU 13:11-12
Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.”
I-explore LUKU 13:11-12
3
LUKU 13:13
Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.
I-explore LUKU 13:13
4
LUKU 13:30
Àwọn èrò ẹ̀yìn yóo di ará iwájú; àwọn ará iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn.”
I-explore LUKU 13:30
5
LUKU 13:25
Nígbà tí baálé ilé bá ti dìde, tí ó bá ti ìlẹ̀kùn, ẹ óo wá dúró lóde, ẹ óo bẹ̀rẹ̀ sí kanlẹ̀kùn, ẹ óo wí pé, ‘Alàgbà, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ṣugbọn yóo da yín lóhùn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí!’
I-explore LUKU 13:25
6
LUKU 13:5
Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”
I-explore LUKU 13:5
7
LUKU 13:27
Ṣugbọn yóo sọ fun yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi.’
I-explore LUKU 13:27
8
LUKU 13:18-19
Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.”
I-explore LUKU 13:18-19
Home
Biblia
Mga Gabay
Mga Palabas