JẸNẸSISI 39

39
Josẹfu ati Aya Pọtifari
1Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba. 2OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere.#A. Apo 7:9 3Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé. 4Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀. 5Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu. 6Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ.
Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà. 7Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀. 8Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi. 9Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” 10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀.
11Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. 12Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé. 13Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé, 14ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo. 15Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.”
16Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé. 17Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí, 18ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.”
19Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi, 20ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́. 21Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé.#A. Apo 7:9. 22Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe. 23Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.

ที่ได้เลือกล่าสุด:

JẸNẸSISI 39: YCE

เน้นข้อความ

แบ่งปัน

คัดลอก

None

ต้องการเน้นข้อความที่บันทึกไว้ตลอดทั้งอุปกรณ์ของคุณหรือไม่? ลงทะเบียน หรือลงชื่อเข้าใช้

วิดีโอสำหรับ JẸNẸSISI 39