Gẹn 10

10
Ìran Àwọn Ọmọ Noa
(I. Kro 1:5-23)
1IRAN awọn ọmọ Noa ni wọnyi, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti: ati fun wọn li a si bí ọmọ lẹhin kíkun-omi.
2Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi.
3Ati awọn ọmọ Gomeri, Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.
4Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.
5Lati ọdọ awọn wọnyi li a ti pín erekuṣu awọn orilẹ-ède ni ilẹ wọn, olukuluku gẹgẹ bi ohùn rẹ̀; gẹgẹ bi idile wọn, li orilẹ-ède wọn.
6Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani.
7Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka; ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani.
8Kuṣi si bí Nimrodu: on si bẹ̀rẹ si idi alagbara li aiye.
9On si ṣe ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA: nitori na li a ṣe nwipe, Gẹgẹ bi Nimrodu ogbóju ọdẹ niwaju OLUWA.
10Ipilẹṣẹ ijọba rẹ̀ ni Babeli, ati Ereki, ati Akkadi, ati Kalne, ni ilẹ Ṣinari.
11Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó.
12Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla.
13Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,
14Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu.
15Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,
16Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,
17Ati awọn ara Hiffi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,
18Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati; lẹhin eyini ni idile awọn ara Kenaani tàn kalẹ.
19Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa.
20Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn.
21Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ.
22Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.
23Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi.
24Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi.
25Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.
26Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,
27Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,
28Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,
29Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani.
30Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn.
31Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn.
32Wọnyi ni idile awọn ọmọ Noa, gẹgẹ bi iran wọn, li orilẹ-ède wọn: lati ọwọ́ awọn wọnyi wá li a ti pín orilẹ-ède aiye lẹhin kíkun-omi.

Nu markerat:

Gẹn 10: YBCV

Märk

Dela

Kopiera

None

Vill du ha dina höjdpunkter sparade på alla dina enheter? Registrera dig eller logga in