1
Mat 13:23
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.
Comparar
Explorar Mat 13:23
2
Mat 13:22
Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.
Explorar Mat 13:22
3
Mat 13:19
Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na.
Explorar Mat 13:19
4
Mat 13:20-21
Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan. Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀.
Explorar Mat 13:20-21
5
Mat 13:44
Ijọba ọrun si dabi iṣura ti a fi pamọ́ sinu oko, ti ọkunrin kan ri, ti o pa a mọ́; nitori ayọ̀ rẹ̀, o lọ, o si ta gbogbo ohun ti o ni, o si rà oko na.
Explorar Mat 13:44
6
Mat 13:8
Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.
Explorar Mat 13:8
7
Mat 13:30
Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi.
Explorar Mat 13:30
Início
Bíblia
Planos
Vídeos