Gẹn 1
1
Ìtàn bí a ṣe dá ayé
1Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye.
2Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi.
3Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà.
4Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun.
5Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini.
6Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi.
7Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃.
8Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji.
9Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃.
10Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara.
11Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃.
12Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
13Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta.
14Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún:
15Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃.
16Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu.
17Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ,
18Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara.
19Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin.
20Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun.
21Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
22Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ.
23Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun.
24Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃.
25Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.
26Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ.
27Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn.
28Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ.
29Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun.
30Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃.
31Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.
Nu geselecteerd:
Gẹn 1: YBCV
Markering
Deel
Kopiëren
Wil je jouw markerkingen op al je apparaten opslaan? Meld je aan of log in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.