1
Gẹnẹsisi 26:3
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀.
Bandingkan
Selidiki Gẹnẹsisi 26:3
2
Gẹnẹsisi 26:4-5
Èmi yóò sọ ìran rẹ di púpọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fi gbogbo ilẹ̀ yìí fún irú àwọn ọmọ rẹ, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí tí Abrahamu gba ohùn mi gbọ́, ó sì pa gbogbo ìkìlọ̀, àṣẹ, ìlànà àti òfin mi mọ́.”
Selidiki Gẹnẹsisi 26:4-5
3
Gẹnẹsisi 26:22
Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, OLúWA ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.”
Selidiki Gẹnẹsisi 26:22
4
Gẹnẹsisi 26:2
OLúWA sì fi ara han Isaaki, ó sì wí pé, “Má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti: Jókòó ní ilẹ̀ tí èmi ó fún ọ.
Selidiki Gẹnẹsisi 26:2
5
Gẹnẹsisi 26:25
Isaaki sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe orúkọ OLúWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì gbẹ́ kànga kan níbẹ̀.
Selidiki Gẹnẹsisi 26:25
Halaman Utama
Alkitab
Pelan
Video