1
JOHANU 3:16
Yoruba Bible
Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.
Mampitaha
Mikaroka JOHANU 3:16
2
JOHANU 3:17
Nítorí Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti dá aráyé lẹ́bi bíkòṣe pé kí aráyé lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ìgbàlà.
Mikaroka JOHANU 3:17
3
JOHANU 3:3
Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.”
Mikaroka JOHANU 3:3
4
JOHANU 3:18
A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́.
Mikaroka JOHANU 3:18
5
JOHANU 3:19
Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.
Mikaroka JOHANU 3:19
6
JOHANU 3:30
Dandan ni pé kí òun túbọ̀ jẹ́ pataki sí i, ṣugbọn kí jíjẹ́ pataki tèmi máa dínkù.”
Mikaroka JOHANU 3:30
7
JOHANU 3:20
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀.
Mikaroka JOHANU 3:20
8
JOHANU 3:36
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀.
Mikaroka JOHANU 3:36
9
JOHANU 3:14
Bí Mose ti gbé ejò sókè ní aṣálẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé Ọmọ-Eniyan sókè
Mikaroka JOHANU 3:14
10
JOHANU 3:35
Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.
Mikaroka JOHANU 3:35
Fidirana
Baiboly
Planina
Horonan-tsary