Luku 17

17
Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́
1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. 2Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. 3 Ẹ máa kíyèsára yín.
“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. 4Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”
5 Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.”
6Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.
7 “Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’? 8 Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’? 9Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. 10Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ”
Ìwòsàn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá
11 Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. 12 Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: 13 Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”
14 Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.
15Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. 16Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.
17Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? 18A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” 19 Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
Bíbọ̀ ìjọba Ọlọ́run
20 Nígbà tí àwọn Farisi bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú ààmì: 21Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsi i níhìn-ín!’ tàbí ‘Kíyèsi i lọ́hùn ún ni!’ sá à wò ó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”
22 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin yóò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i. 23 Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìn-ín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. 24 Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apá kan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀. 25 Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.
26 “Bí ó ti rí ní ọjọ́ Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn. 27Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.
28 “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé; 29Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.
30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ ènìyàn yóò farahàn. 31 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má ṣe sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn. 32 Ẹ rántí aya Lọti. 33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là. 34 Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 35Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 36Ènìyàn méjì yóò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”
37 Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni igún ìkójọpọ̀ sí.”

ಪ್ರಸ್ತುತ ಆಯ್ಕೆ ಮಾಡಲಾಗಿದೆ:

Luku 17: YCB

Highlight

ಶೇರ್

ಕಾಪಿ

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in