1
JẸNẸSISI 4:7
Yoruba Bible
Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”
Bandingkan
Telusuri JẸNẸSISI 4:7
2
JẸNẸSISI 4:26
Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA.
Telusuri JẸNẸSISI 4:26
3
JẸNẸSISI 4:9
OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”
Telusuri JẸNẸSISI 4:9
4
JẸNẸSISI 4:10
OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí.
Telusuri JẸNẸSISI 4:10
5
JẸNẸSISI 4:15
Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á.
Telusuri JẸNẸSISI 4:15
Beranda
Alkitab
Rencana
Video