1
Gẹn 37:5
Bibeli Mimọ
Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i.
Összehasonlít
Fedezd fel: Gẹn 37:5
2
Gẹn 37:3
Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u.
Fedezd fel: Gẹn 37:3
3
Gẹn 37:4
Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia.
Fedezd fel: Gẹn 37:4
4
Gẹn 37:9
O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi.
Fedezd fel: Gẹn 37:9
5
Gẹn 37:11
Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.
Fedezd fel: Gẹn 37:11
6
Gẹn 37:6-7
O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá. Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi.
Fedezd fel: Gẹn 37:6-7
7
Gẹn 37:20
Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri.
Fedezd fel: Gẹn 37:20
8
Gẹn 37:28
Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti.
Fedezd fel: Gẹn 37:28
9
Gẹn 37:19
Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá.
Fedezd fel: Gẹn 37:19
10
Gẹn 37:18
Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a.
Fedezd fel: Gẹn 37:18
11
Gẹn 37:22
Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ.
Fedezd fel: Gẹn 37:22
Kezdőoldal
Biblia
Tervek
Videók