JOHANU 5
5
Jesu wo Arọ kan Sàn ní Jerusalẹmu
1Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu. 2Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò. 3Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [ 4nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.] 5Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji. 6Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”
7Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.”
8Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.” 9Lẹsẹkẹsẹ ara ọkunrin náà dá, ó ká ẹni rẹ̀, ó bá ń rìn.
Ọjọ́ náà jẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi. 10Àwọn Juu sọ fún ọkunrin tí ara rẹ̀ ti dá yìí pé, “Ọjọ́ Ìsinmi ni òní! Èèwọ̀ ni pé kí o ru ẹní rẹ!”#Neh 13:19; Jer 17:21
11Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó mú mi lára dá ni ó sọ pé kí n ká ẹní mi, kí n máa rìn.”
12Wọ́n bi í pé, “Ta ni ẹni náà tí ó sọ fún ọ pé kí o ru ẹni, kí o máa rìn?”
13Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀.
14Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”
15Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn. 16Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi. 17Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”
18Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.#Ọgb 2:16
Àṣẹ tí Jesu fi ń Ṣiṣẹ́
19Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe. 20Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè. 22Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́, 23kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.
24“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè. 25Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè. 26Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè. 27Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan. 28Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo àwọn òkú tí ó wà ní ibojì yóo gbọ́ ohùn rẹ̀, 29tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi.#Dan 12:2
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jesu
30“Èmi kò lè dá nǹkankan ṣe. Ọ̀rọ̀ Baba mi tí mo bá gbọ́ ni mo fi ń ṣe ìdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí kì í ṣe ìfẹ́ tèmi ni mò ń wá bíkòṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.
31“Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni mò ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi lè má jẹ́ òtítọ́. 32Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi. 33Ẹ ti ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Johanu, ó sì ti jẹ́rìí òtítọ́.#Joh 1:19-27; 3:27-30 34Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà. 35Johanu dàbí fìtílà tí ó ń tàn, tí ó sì mọ́lẹ̀. Ó dùn mọ yín fún àkókò díẹ̀ láti máa yọ̀ ninu ìmọ́lẹ̀ tí ó fi fun yín.#Sir 48:1 36Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́. 37Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí.#Mat 3:17; Mak 1:11; Luk 3:22 38Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́. 39Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.#Bar 4:1 40Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.
41“Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan. 42Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín. 43Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á. 44Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo? 45Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn. 46Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí. 47Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí ó kọ gbọ́, báwo ni ẹ óo ti ṣe gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”
Bible Society of Nigeria © 1900/2010