JOHANU 2

2
Jesu Lọ sí Ibi Igbeyawo Kan ní Kana
1Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀. 2Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà. 3Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!”
4Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.”
5Ìyá rẹ̀ sọ fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ ṣe ohunkohun tí ó bá wí fun yín.”
6Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa. 7Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn. 8Ó bá tún wí fún wọn pé, “Ẹ bù ninu rẹ̀ lọ fún alága àsè.” Wọ́n bá bù ú lọ. 9Nígbà tí alága àsè tọ́ omi tí ó di ọtí wò, láì mọ ibi tí ó ti wá, (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iranṣẹ tí ó bu omi náà mọ̀), alága àsè pe ọkọ iyawo. 10Ó ní, “Ọtí tí ó bá dùn ni gbogbo eniyan kọ́ ń gbé kalẹ̀. Nígbà tí àwọn eniyan bá ti mu ọtí yó tán, wọn á wá gbé ọtí èyí tí kò dára tóbẹ́ẹ̀ wá. Ṣugbọn ìwọ fi àtàtà ọtí yìí pamọ́ di àkókò yìí!”
11Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.
12Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapanaumu, òun, ìyá rẹ̀, àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ bíi mélòó kan.#Mat 4:13
Jesu Lòdì sí Lílò tí Wọn Ń Lo Tẹmpili Bí Ọjà
(Mat 21:12-13; Mak 11:15-17; Luk 19:45-46)
13Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu.#Eks 12:1-27 14Ó rí àwọn tí ń ta mààlúù, aguntan, ati ẹyẹlé ninu àgbàlá Tẹmpili, ati àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó. 15Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú. 16Ó sọ fún àwọn tí ń ta ẹyẹlé pé, “Ẹ gbé gbogbo nǹkan wọnyi kúrò níhìn-ín, ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!” 17Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí, “Ìtara ilé rẹ ti jẹ mí lógún patapata.”#O. Daf 69:9
18Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?”
19Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.”#Mat 26:61; 27:40; Mak 14:58; 15:29
20Àwọn Juu wí fún un pé, “Aadọta ọdún ó dín mẹrin ni ó gbà wá láti kọ́ Tẹmpili yìí, ìwọ yóo wá kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta?”
21Ṣugbọn ara rẹ̀ ni ó ń sọ̀rọ̀ bá, tí ó pè ní Tẹmpili. 22Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.
Jesu Mọ Inú Gbogbo Eniyan
23Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe. 24Ṣugbọn Jesu fúnrarẹ̀ kò gbára lé wọn, nítorí ó mọ gbogbo eniyan. 25Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un nípa ọmọ aráyé nítorí ó mọ ohun tí ó wà ninu wọn.

נבחרו כעת:

JOHANU 2: YCE

הדגשה

שתף

העתק

None

רוצים לשמור את ההדגשות שלכם בכל המכשירים שלכם? הירשמו או היכנסו