1
LUKU 11:13
Yoruba Bible
Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”
Compare
Explore LUKU 11:13
2
LUKU 11:9
“Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.
Explore LUKU 11:9
3
LUKU 11:10
Nítorí gbogbo ẹni tí ó bá bèèrè ni yóo rí gbà; ẹni tí ó bá wá kiri yóo rí; ẹni tí ó bá sì kan ìlẹ̀kùn ni a óo ṣí i fún.
Explore LUKU 11:10
4
LUKU 11:2
Ó sọ fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ máa wí pé, ‘Baba, ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé.
Explore LUKU 11:2
5
LUKU 11:4
Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè. Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”
Explore LUKU 11:4
6
LUKU 11:3
Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.
Explore LUKU 11:3
7
LUKU 11:34
Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn.
Explore LUKU 11:34
8
LUKU 11:33
“Kò sí ẹni tí ó jẹ́ tan fìtílà, tí ó jẹ́ fi pamọ́, tabi kí ó fi igbá bò ó. Ńṣe ni yóo gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà kí àwọn tí ó bá ń wọlé lè ríran.
Explore LUKU 11:33
હોમ
બાઇબલ
યોજનાઓ
વિડિઓઝ