JẸNẸSISI 3
3
Ìwà Àìgbọràn
1Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?”#Ọgb 2:24; Ifi 12:19; 20:2
2Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà, 3àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”
4Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá, 5Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”
6Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́. 7Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí.
8Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. 9Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”
10Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”
11Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”
12Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”#2 Kọr 11:3; 1 Tim 2:14.
Ọlọrun Ṣèdájọ́
14OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,
“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,
o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.
Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,
erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,#Ifi 12:17.
ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.
Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,
ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”
16Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,
“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,
ninu ìrora ni o óo máa bímọ.
Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,
òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”
17Ó sọ fún Adamu, pé,
“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,
o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,
mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.
Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
18Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,#Heb 6:8
ewéko ni o óo sì máa jẹ.
19Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,
títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,
nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.
Erùpẹ̀ ni ọ́,
o óo sì pada di erùpẹ̀.”
20Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan. 21OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
Ọlọrun Lé Adamu ati Efa jáde ninu Ọgbà
22Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”#Ifi 22:14. 23Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. 24Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.
Currently Selected:
JẸNẸSISI 3: YCE
Tõsta esile
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010