SAKARAYA 7
7
OLUWA Kọ Ààwẹ̀ Àgàbàgebè
1Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí.
2Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA, 3wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?” 4OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé, 5“Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún? 6Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?”
7Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀?
Àìgbọràn ló fa Ìkólọ-sóko-Ẹrú
8OLUWA tún rán Sakaraya kí ó sọ fún wọn pé, 9“Ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì fi àánú ati ìyọ́nú hàn sí ara yín. 10Ẹ má máa fi ìyà jẹ àwọn opó, tabi àwọn aláìníbaba, tabi àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tabi àwọn aláìní. Ẹ má máa gbèrò ibi sí ẹnikẹ́ni.”
11Ṣugbọn àwọn eniyan kò gbọ́, wọ́n ṣe oríkunkun, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ tèmi. 12Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi. 13“Nígbà tí mo pè wọ́n, wọn kò gbọ́, nítorí náà ni n kò fi ní fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí. 14Bí ìjì líle tí ń fọ́n nǹkan káàkiri bẹ́ẹ̀ ni mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì. Ilẹ̀ dáradára tí wọ́n fi sílẹ̀ di ahoro, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀ mọ́.”
Currently Selected:
SAKARAYA 7: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010