YouVersion Logo
Search Icon

SAKARAYA 13

13
1OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.
2“N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́. 3Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa. 4Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ. 5Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’ 6Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ”
Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Ọlọrun
7OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké.#Mat 26:31; Mak 14:27 8Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí. 9N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ”

Currently Selected:

SAKARAYA 13: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in