YouVersion Logo
Search Icon

DIUTARONOMI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Diutaronomi jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ìmọ̀ràn ati ìjíròrò tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ní ilẹ̀ Moabu, níbi tí wọ́n tẹ̀dó sí lákòókò ìrìn àjò wọn ninu aṣálẹ̀, tí ó sì kù dẹ̀dẹ̀ kí wọ́n wọ ilẹ̀ Kenaani.
Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí ó wà ninu ìwé náà nìyí: (1) Mose sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pataki tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Ó rọ àwọn eniyan náà láti ranti bí Ọlọrun ṣe darí wọn ninu aṣálẹ̀, kí wọn gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí wọn sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. (2) Mose ṣàlàyé àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, ó sì tẹnumọ́ òfin kinni pé kí àwọn eniyan náà máa sin OLUWA nìkan tọkàntọkàn. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé lórí àwọn òfin tí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ ìlérí. (3) Ó rán àwọn eniyan náà létí ìtumọ̀ majẹmu tí Ọlọrun bá wọn dá, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe ojúṣe wọn sí Ọlọrun. (4) Ó mẹ́nuba yíyan Joṣua gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kàn láti darí àwọn eniyan Ọlọrun. Mose kọ orin ìyìn sí Ọlọrun láti fi ògo fún un fún òdodo rẹ̀, ó sì tún ya àwọn ẹ̀yà Israẹli sí mímọ́, lẹ́yìn náà ó kú ní Moabu, ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.
Kókó pataki tí ó jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí ni pé Ọlọrun bukun àwọn eniyan rẹ̀ tí ó fẹ́ràn, ó sì gbà wọ́n là. Àwọn eniyan rẹ̀ náà gbọdọ̀ máa ranti èyí, wọ́n gbọdọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kí wọ́n sì máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu, kí wọ́n lè ní ẹ̀mí gígùn, kí ibukun wọn sì máa pọ̀ sí i.
Àwọn ẹsẹ tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ìwé yìí wà ní orí 6, ẹsẹ 4-6. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ni Jesu tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí òfin tí ó ṣe pataki jùlọ: “Fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ ati pẹlu gbogbo agbára rẹ.”
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìjíròrò àkọ́kọ́ tí Mose ṣe 1:1–4:49
Ìjíròrò keji tí Mose ṣe 5:1–26:19
a. Àwọn òfin mẹ́wàá 5:1–10:22
b. Àwọn òfin, ìlànà, ati ìkìlọ̀ 11:1–26:19
Ìgbésẹ̀ fún àtiwọ ilẹ̀ Kenaani 27:1–28:68
Mose rán àwọn ọmọ Israẹli létí majẹmu wọn pẹlu Ọlọrun 29:1–30:20
Àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí Mose sọ 31:1–33:29
Ikú Mose 34:1-12

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy