TIMOTI KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Onigbagbọ, ará apá kan ilẹ̀ Esia tí a lè pè ní Esia kékeré, ní èdè Yoruba (Asia Minor), ni ọdọmọkunrin tí ń jẹ́ Timoti. Juu ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. Ó di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ati olùrànlọ́wọ́ Paulu ninu ìrìn àjò iṣẹ́ ìyìn rere rẹ̀. Nǹkan mẹta pataki ni Paulu mẹ́nubà ninu Ìwé rẹ̀ Kinni sí Timoti.
Lákọ̀ọ́kọ́, ìwé yìí jẹ́ ìkìlọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí ó lòdì ninu ìjọ. Ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ àdàlú èrò àwọn Juu ati ti àwọn tí kì í ṣe Juu. Kókó inú ẹ̀kọ́ tí à ń wí yìí ni pé kìkì ibi ni ayé yìí, ati pé nípa mímọ àṣírí pataki kan ati nípa pípa àwọn èèwọ̀ nípa oúnjẹ mọ́, ati pé kí eniyan má sì gbeyawo, ni eniyan fi lè ní ìgbàlà. Nǹkan keji tí ó tún wà ninu ìwé náà ni àlàyé lórí ìsìn ati ṣíṣe àkóso ìjọ, pẹlu àpèjúwe irú ìwà tí àwọn aṣaaju ati àwọn diakoni ìjọ gbọdọ̀ máa hù. Ní ìparí, Paulu gba Timoti ní ìmọ̀ràn lórí bí ó ṣe lè jẹ́ iranṣẹ rere fún Kristi, ó sì tún ṣe àlàyé lórí iṣẹ́ rẹ̀ sí oríṣìíríṣìí ìṣọ̀wọ́ àwọn ọmọ ìjọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-2
Ẹ̀kọ́ nípa ìjọ ati àwọn olóyè ìjọ 1:3–3:16
Ẹ̀kọ́ fún Timoti nípa iṣẹ́ rẹ̀ 4:1–6:21
Currently Selected:
TIMOTI KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010