YouVersion Logo
Search Icon

Sekariah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Sekariah kìlọ̀ fún àwọn ará Juda pé tí wọ́n bá kọ̀ láti ronúpìwàdà, gbogbo orílẹ̀-èdè àti Jerusalẹmu tí ó jẹ́ ìlú tí ó yàn fẹ́ yóò sọnù. Sekariah ṣe ìbáwí fún àwọn ènìyàn Juda, láti gbà wọ́n níyànjú àti láti gbé wọn ró kí wọn lè parí kíkọ́ tẹmpili. Olúwa sọ fún Juda pé tí wọ́n bá lè yí padà sí òun, òun náà yóò yípadà sí wọn. Àwọn ènìyàn mọ̀ pé Ọlọ́run yóò bùkún àwọn ṣùgbọ́n Sekariah jẹ́ kí ó yé wọn pé ìdájọ́ ni yóò kọ́kọ́ síwájú kí ìbùkún tó tẹ̀lé e. Ìdájọ́ yìí kó ní jẹ́ ọ̀nà láti fi ìyà jẹ wọn bí kò ṣe láti mú wọn yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Àwọn ohun tí ìwé Sekariah yàn láàyò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé, ó ṣe àpapọ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú bí i ìpè sí ìrònúpìwàdà àwọn ìran wòlíì, ìdájọ́ àti ìgbàlà. Ìran wòlíì yìí ni a mọ̀ sí ìṣípayá èyí tí ó fi ń mú àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ́kàn le. Ní pàtàkì ìgbani-níyànjú ló jẹ Sekariah lógún jù nínú ìwé rẹ̀, Ó gbà Juda níyànjú láti tún tẹmpili kọ́. Bákan náà Sekariah tún sọ nípa bíbọ̀ Messia nínú ọláńlá àti nínú ògo rẹ̀ àti wí pé òun ni Ọlọ́run tó ṣe ìlérí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn Babeli. Ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa títóbi Ọlọ́run.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ṣíṣe àlàyé ìbẹ̀rẹ̀ 1.1-6.
ii. Oríṣìíríṣìí àwọn ìṣípayá mẹ́jọ 1.7–6.8.
iii. Ààmì dìde adé Joṣua olórí àlùfáà 6.9-15.
iv. Oore, àánú àti ìbùkún Olúwa 7.1–8.23.
v. Ìdájọ́ àti ìjìyà lórí àwọn orílẹ̀-èdè 9.1–14.21.

Currently Selected:

Sekariah Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in