YouVersion Logo
Search Icon

Romu Ìfáárà

Ìfáárà
Paulu wà ní Kọrinti nínú ìrìnàjò iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ kẹta. Ó ń gbèrò láti lọ sí Romu, ṣùgbọ́n kò tí i dé ibẹ̀ rí. Ó kọ lẹ́tà yìí sí ilé Ọlọ́run láti jẹ́ kí wọn mọ òun. Ó sì sọ ní ṣókí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ìmọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́tà Paulu yìí jẹ èyí ti o léto jùlọ. Ó bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ káríáyé. Júù tàbí àwọn aláìkọlà kò le fi ọwọ́ sọ àyà pé àwọn wẹ̀ yán kànìnkànìn ní iwájú Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti sọ gbogbo wọn di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ fi oore-ọ̀fẹ́ rà wá padà. Paulu ṣe àlàyé ibi tí Ọlọ́run fi àwọn Júù sí nínú èrò rẹ̀ (9–11), ó sì gúnlẹ̀ lẹ́tà rẹ̀ lórí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ nípa ìwà-bí-Ọlọ́run.
Ìwà òdodo Ọlọ́run, iṣẹ́ òdodo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ayé, èrò ìgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ òdodo ni ó dojú ìwé yìí kọ. Ọlọ́run ni a rí bí Ọlọ́run mímọ́ fún gbogbo ayé, òfin rẹ̀ sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀dá rẹ̀. Inú òfin rẹ̀ yìí ni ó ti rán ọmọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo láti ọ̀run kí ó wá kú fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Nísinsin yìí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Jesu gbọ́ ni a ó gbàlà (10.9) tí a ó sì fún ni agbára Ọlọ́run láti borí ẹ̀ṣẹ̀ nínú ìgbé ayé rẹ̀. Láti ipasẹ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ kò sí ohun tó lè ya Kristi ní ipa (8.38,39).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìfáàrà 1.1-17.
ii. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìgbàlà nípa ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Kristi 1.18–5.21.
iii. Ìṣẹ́gun lórí ẹ̀ṣẹ̀ nípa agbára Kristi 6.1–8.39.
iv. Èrò Ọlọ́run fún àwọn Júù 9.1–11.36.
v. Ìpilẹ̀ṣẹ̀ àlàyé ẹ̀kọ́ Kristi náà 12.1–15.13.
vi. Ohun tó kíyèsi gbẹ̀yìn 15.14–16.27.

Currently Selected:

Romu Ìfáárà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in