YouVersion Logo
Search Icon

Lefitiku Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Lefitiku jẹ́ orúkọ mọ́ àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ àlùfáà nínú tẹmpili tí wọ́n ní àkànṣe iṣẹ́ tí wọn ń ṣe nínú tẹmpili. Wọ́n jẹ́ ẹ̀yà tí a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ nínú tẹmpili. Ìwé Eksodu fi ìlànà kíkọ́ tẹmpili lélẹ̀ nígbà tí ìwé Lefitiku fi àwọn òfin tí wọn yóò máa tẹ̀lé ní sí sin Ọlọ́run lélẹ̀. Àwọn òfin yìí ni Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lórí òkè Sinai láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ̀.
Kókó kan pàtàkì tí ìwé Lefitiku tẹnumọ́ ni jíjẹ́ mímọ́: Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, àwọn ènìyàn rẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn, gbogbo ẹran tí wọn yóò fi rú ẹbọ sí Ọlọ́run gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́, gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá bí obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù, ọkùnrin tó ní ààrùn ni kò gbọdọ̀ wọ inú àgọ́ àjọ, a gbọdọ̀ lé wọn padà bí a ṣe lé Adamu àti Efa nínú ọgbà Edeni. Ìwé yìí fi ìlànà ìwẹ̀nùmọ́ lélẹ̀ fún àwọn ohun tí kò mọ́. Ó sọ nípa onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà pa àṣẹ Olúwa mọ́ àti májẹ̀mú rẹ̀ nípa ohun ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ rírú sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti sin Olúwa Ọlọ́run ní abẹ́ ìdarí àwọn àlùfáà rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìrúbọ pàtàkì márùn-ún 1–7.
ii. Ìfinijoyè, iṣẹ́ àti àwọn ọmọ Aaroni 8–10.
iii. Àwọn òfin: ìmọ́tótó-oúnjẹ, ìbímọ, àìsàn. 11–15.
iv. Ọjọ́ ìyàsímímọ́ àti iṣẹ́ ilé Olúwa 16–17.
v. Àwọn òfin tí ó wà fún; sísun tùràrí, jíjẹ́ olóòtítọ́, olè jíjà, òrìṣà sí sìn. 18–20.
vi. Àwọn ìlànà tí ó wà fún àwọn àlùfáà, ìrúbọ, àti àjọ̀dún ìkórè 21.1–24.9.
vii. Ìjìyà fún ìṣọ̀rọ̀-òdì, ìpànìyàn. 24.10-23.
viii. Ọdún ìsinmi, ayẹyẹ àti kíkúrò lóko ẹrú 25.
ix. Ìbùkún, àti ègún fún ìgbọ́ràn àti àìgbọ́ràn sí májẹ̀mú. 26.
x. Ìlànà fún ẹ̀jẹ́ ọrẹ ẹbọ fún Olúwa 27.

Currently Selected:

Lefitiku Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in