Isaiah 35
35
Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà
1Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn;
aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.
Gẹ́gẹ́ bí ewéko,
2Ní títanná yóò tanná;
yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin.
Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un,
ẹwà Karmeli àti Ṣaroni;
wọn yóò rí ògo Olúwa,
àti ẹwà Ọlọ́run wa.
3 Fún ọwọ́ àìlera lókun,
mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:
4Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé
“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;
Ọlọ́run yín yóò wá,
òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san;
pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́
òun yóò wá láti gbà yín là.”
5 Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú
àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.
6Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,
àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.
Odò yóò tú jáde nínú aginjù
àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
7Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà,
ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.
Ní ibùgbé àwọn dragoni,
níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀,
ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.
8Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀:
a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́.
Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;
yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà,
àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.
9Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,
tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀;
a kì yóò rí wọn níbẹ̀.
Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,
10àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin;
ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.
Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,
ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Currently Selected:
Isaiah 35: YCB
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.