YouVersion Logo
Search Icon

Isaiah 11

11
Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese
1 Èèkàn kan yóò sọ láti ibi
kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan
yóò ti so èso.
2 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e
ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára
ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
3Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.
Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
4Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
5 Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
6 Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
7Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
8Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
9Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.
12Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
13Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
Efraimu kò ní jowú Juda,
tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
14Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
15 Olúwa yóò sọ di gbígbé
àyasí Òkun Ejibiti,
pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
kọjá lórí odò Eufurate.
Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
16Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.

Currently Selected:

Isaiah 11: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in