YouVersion Logo
Search Icon

Oniwaasu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Òǹkọ̀wé ìwé Oniwaasu jẹ́ kí a rí i dájú wí pé, òun ní ìmọ̀ nínú ìwòye ayé láàrín àkókò ìbí àti ikú, èyí tó tayọ ìmọ̀ ènìyàn tí ènìyàn kò sì le è rí. Nínú ìwòye rẹ̀, ó gbé ìwọ̀n ọmọ ènìyàn wò, ó sì wo agbára wọn. Ó rí òye ènìyàn pé, kódà àwọn tó jẹ́ ti Ọlọ́run ní òpin, kò sì le è rí pàtàkì agbára Ọlọ́run tàbí mọ bí ó ṣe dá ènìyàn. Ó tún tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé, ènìyàn máa fi òmùgọ̀ wá ohun kan tàbí òmíràn, wọ́n ń ṣe làálàá bí ẹni pé wọ́n lè mọ gbogbo ayé, wọn a máa wòye àyànmọ́ ara wọn. Nítorí nípa wíwo àwọn ohun wọ̀nyí, “Asán ni gbogbo rẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo” (1.14). Ṣùgbọ́n ó fi ìgbàgbọ́ kọ ọ́ pé: Ọlọ́run ló ni ohun gbogbo tí ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀ ti ń fẹ́. Fún ìdí èyí ènìyàn gbọdọ̀ ní sùúrù láti gbádùn ayé bí Ọlọ́run ṣe fi fún un.
Ó ń tọ́ka sí í pé asán ni ayé yìí jẹ́, àti wí pé láìní Ọlọ́run, ohunkóhun kò lè tẹ́ ènìyàn lọ́rùn. Nítorí nípa rẹ̀ ni gbogbo ayé àti àwọn ẹ̀bùn ohun rere mìíràn ṣe lè tó ènìyàn lọ́wọ́, tí yóò sì gbádùn rẹ̀ títí dé òpin. Ní pàtàkì, ìwé yìí fi ìgbé ayé ọkùnrin tí ó wà ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ hàn, èyí tí púpọ̀ nínú ìgbé ayé rẹ̀ jẹ́ asán, ìmúlẹ̀mófo nítorí kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, èyí tí kò sì yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Òǹkọ̀wé. 1.1.
ii. Asán ni agbára ènìyàn tí kò ní Ọlọ́run nínú ayé. 1.2.
iii. Àìní èrè ni kíkó ohun tí yóò mú ayọ̀ ayé wá jọ. 1.3-11.
iv. Ó yẹ kí o jẹ ìgbádùn rẹ̀ nítorí pé o jẹ ẹ̀bùn Ọlọ́run. 1.1–11.6.
v. Ìgbà ogbó àti ikú yóò dé, ènìyàn gbọdọ̀ gbádùn ayé nígbà èwe rẹ̀. 11.7–12.7.
vi. Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí i. 12.8-14.

Currently Selected:

Oniwaasu Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in