YouVersion Logo
Search Icon

Oniwaasu 11

11
Àkàrà lórí omi
1Fún àkàrà rẹ sórí omi,
nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà
2Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,
nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀.
3Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi,
ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí
Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá
níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.
4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.
5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́
tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run
ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere
bóyá èyí tàbí ìyẹn
tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.
Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ
7Ìmọ́lẹ̀ dùn;
Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.
8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún
tí ó le è lò láyé
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn
nítorí wọn ó pọ̀
Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.
9Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe
kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.
Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ
àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí
ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni
Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.
10Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ
kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò
nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.

Currently Selected:

Oniwaasu 11: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in