YouVersion Logo
Search Icon

1 Ọba Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwọn ìwé Samuẹli. Ó fúnka mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣèjọba ní ìlànà májẹ̀mú Ọlọ́run. Àwọn wòlíì jẹ́ atọ́nisọ́nà fún àwọn ọba lórí ìṣàkóso wọn. Bákan náà ni wọ́n ń fún àwọn ọba wọ̀nyí ní ìmọ̀ràn àti ọ̀rọ̀ ìyànjú láti máa tẹ̀lé májẹ̀mú Ọlọ́run. Àánú Ọlọ́run wà lórí àwọn ọba tó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ìlérí Ọlọ́run wà fún wọn pẹ̀lú (1 Ọba 9.1-9). Ìdájọ́ Ọlọ́run sì dájú lórí àwọn tó ń ṣe àìgbọ́ràn sí májẹ̀mú Ọlọ́run, ojú Ọlọ́run sì korò sí wọn pẹ̀lú.
Gbogbo ìyànjú àti akitiyan ọba kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ ní Israẹli àti Juda ni ó sọ ohun rere àti ohun búburú tí wọ́n ṣe. Àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ọba kọ̀ọ̀kan sì wà nínú ìwé ìran rẹ̀.
Dafidi di arúgbó, Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní Israẹli. Ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọba tí òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri gbogbo àgbáyé. Ó kọ́ tẹmpili Olúwa, ó sì kọ́ ààfin ọba pẹ̀lú: A pín ìjọba sí méjì (12.16-33). Àwọn ọba jẹ ní Israẹli àti ní Juda, àwọn kan ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àwọn kan kò sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Elijah kó ipa ribiribi lórí ìdàgbàsókè Israẹli àti Juda, wọ́n ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún ògo Ọlọ́run (17.17-24), wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ́gun fún àwọn ọba tó pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ (20.13-15), bákan náà ni wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú fún àwọn ọba tó lòdì sí májẹ̀mú Ọlọ́run (22.29-40).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìjọba Dafidi dé òpin 1.1–1.31.
ii. Solomoni jẹ ọba 1.32–2.46.
iii. Àkókò ìjọba Solomoni 3.1–11.43.
iv Àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn Solomoni 12.1–16.34.
v. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Elijah àti Eliṣa àti àwọn wòlíì mìíràn 17.1–22.53.

Currently Selected:

1 Ọba Ìfáàrà: YCB

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in