Sek 8
8
Ọlọrun ṣèlérí láti Dá Ibukun Jerusalẹmu Pada
1Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe,
2Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u.
3Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.
4Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, arugbo ọkunrin ati arugbo obinrin, yio sa gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku ti on ti ọ̀pa li ọwọ rẹ̀ fun ogbó.
5Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti nṣire ni ita wọn.
6Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, bi o ba ṣe iyanu li oju iyokù awọn enia yi li ọjọ wọnyi, iba jẹ iyanu li oju mi pẹlu bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
7Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama;
8Emi o si mu wọn wá, nwọn o si ma gbe ãrin Jerusalemu: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, li otitọ, ati li ododo.
9Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili.
10Nitori pe ṣãju ọjọ wọnni ọya enia kò to nkan, bẹni ọ̀ya ẹran pẹlu; bẹ̃ni kò si alafia fun ẹniti njade lọ, tabi ẹniti nwọle bọ̀, nitori ipọnju na: nitori mo doju gbogbo enia olukuluku kọ aladugbo rẹ̀.
11Ṣugbọn nisisiyi emi kì yio ṣe si iyokù awọn enia yi gẹgẹ bi ti ìgba atijọ wọnni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
12Nitori irugbin yio gbilẹ: àjara yio so eso rẹ̀, ilẹ yio si hù ọ̀pọlọpọ nkan rẹ̀ jade, awọn ọrun yio si mu irì wọn wá: emi o si mu ki awọn iyokù enia yi ni gbogbo nkan wọnyi.
13Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le.
14Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà.
15Bẹ̃li emi si ti rò ọjọ wọnyi lati ṣe rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda: ẹ má bẹ̀ru.
16Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni.
17Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi.
18Ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tọ̀ mi wá wipe,
19Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia.
20Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Awọn enia yio sa tún wá, ati ẹniti yio gbe ilu-nla pupọ.
21Awọn ẹniti ngbe ilu-nla kan yio lọ si omiran, wipe, Ẹ jẹ ki a yára lọ igbadura niwaju Oluwa, ati lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun: emi pẹlu o si lọ.
22Nitõtọ ọ̀pọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Jerusalemu; ati lati gbadura niwaju Oluwa.
23Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.
Currently Selected:
Sek 8: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.