YouVersion Logo
Search Icon

Sek 11

11
Ìṣubú Àwọn Aninilára
1ṢI ilẹkun rẹ wọnni silẹ, Iwọ Lebanoni, ki iná ba le jẹ igi kedari rẹ run.
2Hu, igi firi; nitori igi kedari ṣubu; nitori ti a ba awọn alagbara jẹ: hu, ẹnyin igi oaku ti Baṣani, nitori a ke igbo ajara lulẹ.
3Ohùn igbe awọn oluṣọ agutan; nitori ogo wọn bajẹ: ohùn bibu awọn ọmọ kiniun; nitori ogo Jordani bajẹ.
Àwọn Olùṣọ́-Aguntan Meji
4Bayi li Oluwa Ọlọrun mi wi; Bọ́ ọwọ́-ẹran abọ́pa.
5Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn.
6Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn.
7Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na.
8Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi.
9Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀.
10Mo si mu ọpa mi, ani Ẹwà, mo si ṣẹ ẹ si meji, ki emi ba le dà majẹmu mi ti mo ti ba gbogbo awọn enia ni da.
11O si dá li ọjọ na; bẹ̃ni awọn otoṣi ninu ọwọ́-ẹran nì ti o duro tì mi mọ̀ pe, ọ̀rọ Oluwa ni.
12Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi.
13Oluwa si wi fun mi pe, Sọ ọ si amọkòko: iye daradara na ti nwọn yọwó mi si. Mo si mu ọgbọ̀n owo fadakà na, mo si sọ wọn si amọkòko ni ile Oluwa.
14Mo si ṣẹ ọpa mi keji, ani Amure, si meji, ki emi ki o le yà ibatan ti o wà lãrin Juda ati lãrin Israeli.
15Oluwa si wi fun mi pe, Tún mu ohun-elò oluṣọ agutan aṣiwere kan sọdọ rẹ.
16Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ.
17Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.

Currently Selected:

Sek 11: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in