YouVersion Logo
Search Icon

O. Sol Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ewì ìfẹ́ ni Orin Solomoni, nítorí ọpọlọpọ orin tí ó wà ninu rẹ̀ jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin ọkunrin kan ati obinrin kan tí wọ́n jẹ́ olólùfẹ́. Àwọn ìwé mìíràn pè é ní Orin Solomoni, nítorí pé àwọn Heberu ka ọ̀rọ̀ orin náà kún orin tí Solomoni kọ. Àwọn mìíràn sì ń pè é ní “Orin tí ó dùn jù lọ.”
Àwọn Juu ń fi ojú àjọṣe láàrin Ọlọrun ati àwọn eniyan rẹ̀ wo àwọn orin wọnyi, ṣugbọn ojú àjọṣe láàrin Kristi ati ìjọ ni àwọn Kristẹni fi wò wọ́n.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Orin kinni 1:1—2:7
Orin keji 2:8—3:5
Orin kẹta 3:6—5:1
Orin kẹrin 5:2—6:3
Orin karun-un 6:4—8:4
Orin kẹfa 8:5-14

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in