O. Sol 5
5
1MO de inu ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo! mo ti kó ojia mi pẹlu õrùn didùn mi jọ; mo ti jẹ afara mi pẹlu oyin mi; mo ti mu ọti-waini mi pẹlu wàra mi: Ẹ jẹun, ẹnyin ọrẹ́; mu, ani mu amuyo, ẹnyin olufẹ.
Orin Kẹrin
2Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru.
3Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́?
4Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i.
5Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà.
6Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn.
7Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi.
8Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi.
9Kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran ti iwọ fi nfi wa bú bẹ̃?
10Olufẹ mi funfun, o si pọn, on ni ọlá jù ọ̀pọlọpọ lọ.
11Ori rẹ̀ dabi wura ti o dara julọ, ìdi irun rẹ̀ dabi imọ̀ ọpẹ, o si du bi ẹiyẹ iwò.
12Oju rẹ̀ dabi àdaba li ẹba odò, ti a fi wàra wẹ̀, ti o si ngbe inu alafia.
13Ẹrẹ̀kẹ rẹ̀ dabi ebè turari, bi olõrùn didùn, ète rẹ̀ bi itanna lili, o nkán ojia olõrùn didùn.
14Ọwọ rẹ̀ dabi oruka wura ti o tò ni berili yika, ara rẹ̀ bi ehin-erin didán ti a fi saffire bò.
15Itan rẹ̀ bi ọwọ̀n marbili, ti a gbe ka ihò ìtẹbọ wura daradara; ìwo rẹ̀ dabi Lebanoni, titayọ rẹ̀ bi igi kedari.
16Ẹnu rẹ̀ dùn rekọja: ani o wunni patapata. Eyi li olufẹ mi, eyi si li ọrẹ mi, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu.
Currently Selected:
O. Sol 5: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.