YouVersion Logo
Search Icon

Rut 3

3
Rutu rí ọkọ fẹ́
1NAOMI iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ọmọbinrin mi, emi ki yio ha wá ibi isimi fun ọ, ki o le dara fun ọ?
2Njẹ nisisiyi ibatan wa ki Boasi iṣe, ọmọbinrin ọdọ ẹniti iwọ ti mbá gbé? Kiyesi i, o nfẹ ọkà-barle li alẹ yi ni ilẹ-ipakà rẹ̀.
3Nitorina wẹ̀, ki o si para, ki o si wọ̀ aṣọ rẹ, ki o si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà: ṣugbọn má ṣe jẹ ki ọkunrin na ki o ri ọ titi on o fi jẹ ti on o si mu tán.
4Yio si ṣe, nigbati o ba dubulẹ, ki iwọ ki o kiyesi ibi ti on o sùn si, ki iwọ ki o wọle, ki o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ki o si dubulẹ; on o si sọ ohun ti iwọ o ṣe fun ọ.
5O si wi fun u pe, Gbogbo eyiti iwọ wi fun mi li emi o ṣe.
6O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u.
7Nigbati Boasi si jẹ ti o si mu tán, ti inu rẹ̀ si dùn, o lọ dubulẹ ni ikangun ikójọ ọkà: on si wá jẹjẹ, o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dubulẹ.
8O si ṣe lãrin ọganjọ ẹ̀ru bà ọkunrin na, o si yi ara pada: si kiyesi i, obinrin kan dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀.
9O si wipe, Iwọ tani? On si dahùn wipe, Emi Rutu ọmọbinrin ọdọ rẹ ni: nitorina nà eti-aṣọ rẹ bò ọmọbinrin ọdọ rẹ; nitori iwọ ni ibatan ti o sunmọ wa.
10On si wipe, Alabukun ni iwọ lati ọdọ OLUWA wá, ọmọbinrin mi: nitoriti iwọ ṣe ore ikẹhin yi jù ti iṣaju lọ, niwọnbi iwọ kò ti tẹle awọn ọmọkunrin lẹhin, iba ṣe talakà tabi ọlọrọ̀.
11Njẹ nisisiyi, ọmọbinrin mi máṣe bẹ̀ru; gbogbo eyiti iwọ wi li emi o ṣe fun ọ: nitori gbogbo agbajọ awọn enia mi li o mọ̀ pe obinrin rere ni iwọ iṣe.
12Njẹ nisisiyi ibatan ti o sunmọ nyin li emi iṣe nitõtọ: ṣugbọn ibatan kan wà ti o sunmọ nyin jù mi lọ.
13Duro li oru yi, yio si ṣe li owurọ̀, bi on o ba ṣe iṣe ibatan si ọ, gẹgẹ; jẹ ki o ṣe iṣe ibatan: ṣugbọn bi kò ba fẹ́ ṣe iṣe ibatan si ọ, nigbana ni emi o ṣe iṣe ibatan si ọ, bi OLUWA ti wà: dubulẹ titi di owurọ̀.
14On si dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀ titi di owurọ̀: o si dide ki ẹnikan ki o to mọ̀ ẹnikeji. On si wipe, Má ṣe jẹ ki a mọ̀ pe obinrin kan wá si ilẹ-ipakà.
15O si wipe, Mú aṣọ-ileke ti mbẹ lara rẹ wá, ki o si dì i mú: nigbati o si dì i mú, o wọ̀n òṣuwọn ọkà-barle mẹfa, o si gbé e rù u: on si wọ̀ ilu lọ.
16Nigbati o si dé ọdọ iya-ọkọ rẹ̀, on wipe, Iwọ tani nì ọmọbinrin mi? O si wi gbogbo eyiti ọkunrin na ṣe fun on fun u.
17O si wipe, Òṣuwọn ọkà-barle mẹfa wọnyi li o fi fun mi; nitori o wi fun mi pe, Máṣe ṣanwọ tọ̀ iya-ọkọ rẹ lọ.
18Nigbana li on wipe, Joko jẹ, ọmọbinrin mi, titi iwọ o fi mọ̀ bi ọ̀ran na yio ti jasi: nitoripe ọkunrin na ki yio simi, titi yio fi pari ọ̀ran na li oni.

Currently Selected:

Rut 3: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in