Rom Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Nítorí ati ṣánnà fún ìbẹ̀wò tí Paulu fẹ́ lọ ṣe sí ìjọ tí ó wà ní Romu, ni ó mú un kọ ìwé tí à ń pè ní Ìwé sí Àwọn Ará Romu. Èrò rẹ̀ ni pé òun óo ṣiṣẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, pẹlu àtìlẹ́yìn wọn, òun óo lọ sí Spania. Ó kọ ìwé sí wọn láti ṣe àlàyé lórí irú òye tí ó ní nípa ẹ̀sìn igbagbọ ati irú àyọrísí tí ó yẹ kí ẹ̀sìn yìí ní ninu ìgbé-ayé onigbagbọ. Ninu ìwé yìí ni Paulu ti ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ jùlọ nípa iṣẹ́ tí ó ní láti jẹ́.
Lẹ́yìn tí Paulu ti kí àwọn eniyan inú ìjọ ní Romu tí ó sì sọ fún wọn nípa bí ó ṣe ń gbadura fún wọn, ó sọ ohun tí ó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí wọn pé: ìyìn rere fi hàn wá bí Ọlọrun ti ṣe mú kí nǹǹkan dọ́gba láàrin àwọn eniyan ati ara rẹ̀. Igbagbọ ni okùnfà ìdọ́gba yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin (1:17).
Lẹ́yìn náà, Paulu bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ yìí pé: ati Juu ni, ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni, gbogbo eniyan ló yẹ kí ààrin àwọn ati Ọlọrun dọ́gba, nítorí pé bákan náà ni gbogbo wọn jọ wà lábẹ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Igbagbọ ninu Jesu ni ó ń mú ìdọ́gba wá láàrin Ọlọrun ati eniyan. Ohun tí Paulu tún mẹ́nu bà lẹ́yìn èyíi ni àlàyé lórí ìgbé-ayé titun tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Jesu, tí àwọn onigbagbọ máa ń ní, nítorí pé nǹǹkan dọ́gba láàrin àwọn ati Ọlọrun. Onigbagbọ ní alaafia pẹlu Ọlọrun, ẹ̀mí Ọlọrun sì fún un ní ìdáǹdè kúrò ninu agbára ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ikú. Ninu orí karun-un títí dé orí kẹjọ, Paulu ṣe àlàyé lórí ohun tí Òfin wà fún, ati agbára Ẹ̀mí Ọlọrun ninu ìgbé-ayé onigbagbọ. Lẹ́yìn èyíi Paulu gbìyànjú láti ṣe àlàyé lórí ààyè tí àwọn Juu ati àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wà ninu ètò Ọlọrun fún gbogbo eniyan. Ohun tí ó fi ká àlàyé rẹ̀ lẹ́sẹ̀ ni pé, kíkọ̀ tí àwọn Juu kọ Jesu jẹ́ ara ètò Ọlọrun láti mú oore-ọ̀fẹ́ Jesu wá sí àrọ́wọ́tó gbogbo eniyan. Ó gbàgbọ́ pé kíkọ̀ tí àwọn Juu kọ Jesu kì í ṣe ọ̀rọ̀ títí laelae. Ní ìparí, Paulu sọ̀rọ̀ lórí irú ìgbé-ayé tí ó yẹ kí onigbagbọ máa gbé, pataki jùlọ nípa bí ó ti yẹ láti fi ìfẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò. Ó tún mẹ́nu ba àwọn kókó ọ̀rọ̀ iṣẹ́ onigbagbọ sí Ọlọrun, sí ìjọba, ati sí àwọn ẹlòmíiràn. Ó sì tún mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ ẹ̀rí-ọkàn pẹlu. Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ ati ìyìn Ọlọrun ni ó fi kásẹ̀ ìwé náà nílẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju ati kókó ọ̀rọ̀ ìwé náà 1:1-17
Bí eniyan ṣe nílò ìgbàlà 1:18—3:20
Ọ̀nà tí Ọlọrun là sílẹ̀ fún ìgbàlà 3:21—4:25
Ìgbé-ayé titun ninu Kristi 5:1—8:39
Israẹli ninu ètò Ọlọrun 9:1—11:36
Ìwà onigbagbọ 12:1—15:13
Ọ̀rọ̀ ìparí ati ìkíni 15:14—16:27
Currently Selected:
Rom Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.