YouVersion Logo
Search Icon

Rom 8:5-11

Rom 8:5-11 YBCV

Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí. Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: Nitori ero ti ara ọtá ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e. Bẹ̃li awọn ti o wà ninu ti ara, kò le wù Ọlọrun. Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀. Bi Kristi ba si wà ninu nyin, ara jẹ okú nitori ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn ẹmí jẹ iyè nitori ododo. Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu.