Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu: Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo. Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun. Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba, Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ. O si tún wipe, Ẹnyin Keferi, ẹ mã yọ̀ pẹlu awọn enia rẹ̀. Ati pẹlu, Ẹ yìn Oluwa gbogbo ẹnyin Keferi; ẹ si kokikí rẹ̀, ẹnyin enia gbogbo. Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si. Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.
Read Rom 15
Listen to Rom 15
Share
Compare All Versions: Rom 15:5-13
Save verses, read offline, watch teaching clips, and more!
YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy
Home
Bible
Plans
Videos