YouVersion Logo
Search Icon

Ifi 7:9-12

Ifi 7:9-12 YBCV

Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn; Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan. Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun, Wipe, Amin: Ibukún, ati ogo, ati ọgbọ́n, ati ọpẹ́, ati agbara, ati ipá fun Ọlọrun wa lai ati lailai. Amin.