YouVersion Logo
Search Icon

Ifi 22

22
1O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.
2Li ãrin igboro rẹ̀, ati niha ikini keji odò na, ni igi iye gbé wà, ti ima so onirũru eso mejila, a si mã so eso rẹ̀ li oṣõṣù: ewé igi na si ni fún mimú awọn orilẹ-ède larada.
3Ègún kì yio si si mọ́: itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan ni yio si mã wà nibẹ̀; awọn iranṣẹ rẹ̀ yio si ma sìn i:
4Nwọn o si mã ri oju rẹ̀; orukọ rẹ̀ yio si mã wà ni iwaju wọn.
5Oru kì yio si si mọ́; nwọn kò si ni iwá imọlẹ fitila, tabi imọlẹ õrùn; nitoripe Oluwa Ọlọrun ni yio tan imọlẹ fun wọn: nwọn o si mã jọba lai ati lailai.
Dídé Kristi
6O si wi fun mi pe, ododo ati otitọ li ọ̀rọ wọnyi: Oluwa Ọlọrun ẹmi awọn woli li o si rán angẹli rẹ̀ lati fi ohun ti kò le ṣaiṣẹ kánkán hàn awọn iranṣẹ rẹ̀.
7 Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́.
8Emi Johanu li ẹniti o gbọ́ ti o si ri nkan wọnyi. Nigbati mo si gbọ́ ti mo si ri, mo wolẹ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli na, ti o fi nkan wọnyi hàn mi.
9Nigbana li o wi fun mi pe, Wo o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ woli, ati ti awọn ti npa ọ̀rọ inu iwe yi mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun.
10O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi di ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀.
11Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó.
12 Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán; ère mi si mbẹ pẹlu mi, lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀ yio ti ri.
13 Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin.
14Ibukún ni fun awọn ti nfọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na, ati ki nwọn ki o le gba awọn ẹnubode wọ inu ilu na.
15 Nitori li ode ni awọn ajá gbé wà, ati awọn oṣó, ati awọn àgbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke.
16 Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn.
17Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ.
18Emi njẹri fun olukuluku ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ iwe yi pe, Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u.
19Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọ̀rọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìye, ati kuro ninu ilu mimọ́ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi.
20Ẹniti o jẹri nkan wọnyi wipe, Nitõtọ emi mbọ̀ kánkán. Amin. Mã bọ̀, Jesu Oluwa.
21Ore-ọfẹ Jesu Oluwa ki o wà pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́. Amin.

Currently Selected:

Ifi 22: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in