Ifi 21:4-5
Ifi 21:4-5 YBCV
Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ. Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn.