O. Daf 94
94
Ọlọrun Onídàájọ́ Gbogbo Ayé
1OLUWA, Ọlọrun ẹsan; Ọlọrun ẹsan, fi ara rẹ hàn.
2Gbé ara rẹ soke, iwọ onidajọ aiye: san ẹsan fun awọn agberaga.
3Oluwa, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu yio fi ma leri?
4Nwọn o ti ma dà ọ̀rọ nù ti nwọn o ma sọ ohun lile pẹ to? ti gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio fi ma fi ara wọn leri.
5Oluwa, nwọn fọ́ awọn enia rẹ tutu, nwọn si nyọ awọn enia-ini rẹ lẹnu.
6Nwọn pa awọn opó ati alejo, nwọn si pa awọn ọmọ alaini-baba.
7Sibẹ nwọn wipe, Oluwa kì yio ri i, bẹ̃li Ọlọrun Jakobu kì yio kà a si,
8Ki oye ki o ye nyin, ẹnyin ope ninu awọn enia: ati ẹnyin aṣiwere, nigbawo li ẹnyin o gbọ́n?
9Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran?
10Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ.
11Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn.
12Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá;
13Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu.
14Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ.
15Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin.
16Tani yio dide si awọn oluṣe buburu fun mi? tabi tani yio dide si awọn oniṣẹ ẹ̀ṣe fun mi?
17Bikoṣe bi Oluwa ti ṣe oluranlọwọ mi; ọkàn mi fẹrẹ joko ni idakẹ.
18Nigbati mo wipe, Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, ãnu rẹ dì mi mu.
19Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu rẹ li o nmu inu mi dùn.
20Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika?
21Nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si ọkàn olododo, nwọn si da ẹ̀jẹ alaiṣẹ lẹbi.
22Ṣugbọn Oluwa li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi,
23On o si mu ẹ̀ṣẹ wọn bọ̀ sori ara wọn, yio si ke wọn kuro ninu ìwa-buburu wọn: Oluwa Ọlọrun wa, yio ke wọn kuro.
Currently Selected:
O. Daf 94: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.