YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 92

92
Orin Ìyìn
Orin fun ọjọ isimi.
1OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo:
2Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ.
3Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu.
4Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ.
5Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi.
6Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia.
7Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni:
8Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai.
9Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka.
10Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori.
11Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi.
12Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.
13Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa.
14Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini;
15Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.

Currently Selected:

O. Daf 92: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in