O. Daf 89
89
Majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi
1EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran.
2Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun.
3Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi,
4Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran,
5Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ.
6Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa?
7Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká.
8Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká.
9Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ.
10Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká.
11Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn.
12Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ.
13Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ.
14Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ.
15Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ.
16Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke.
17Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke,
18Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa.
19Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia.
20Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori:
21Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le.
22Ọtá kì yio bère lọdọ rẹ̀; bẹ̃ni awọn ọmọ iwà-buburu kì yio pọ́n ọ loju.
23Emi o si lu awọn ọta rẹ̀ bolẹ niwaju rẹ̀, emi o si yọ awọn ti o korira rẹ̀ lẹnu.
24Ṣugbọn otitọ mi ati ãnu mi yio wà pẹlu rẹ̀; ati li orukọ mi li a o gbé iwo rẹ̀ soke.
25Emi o gbé ọwọ rẹ̀ le okun, ati ọwọ ọtún rẹ̀ le odò nla nì.
26On o kigbe pè mi pe, Iwọ ni baba mi, Ọlọrun mi, ati apata igbala mi.
27Emi o si ṣe e li akọbi, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ.
28Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin.
29Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun.
30Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi;
31Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́,
32Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna.
33Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀.
34Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada.
35Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi.
36Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi.
37A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun.
Ìlérí Ọlọrun fun Dafidi
38Ṣugbọn iwọ ti ṣa tì, iwọ si korira, iwọ ti binu si Ẹni-ororo rẹ.
39Iwọ ti sọ majẹmu iranṣẹ rẹ di ofo: iwọ ti sọ ade rẹ̀ si ilẹ.
40Iwọ ti fa ọgba rẹ̀ gbogbo ya: iwọ ti mu ilu-olodi rẹ̀ di ahoro.
41Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀.
42Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀.
43Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun.
44Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ.
45Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o.
Adura ìdáǹdè
46Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi?
47Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan?
48Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú.
49Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ?
50Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia.
51Ti awọn ọta rẹ fi kẹgàn, Oluwa: ti nwọn fi ngàn ipasẹ Ẹni-ororo rẹ.
52Olubukún ni Oluwa si i titi lailai. Amin ati Amin.
IWE IV
Currently Selected:
O. Daf 89: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.