YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 85

85
Adura Ire Orílẹ̀-Èdè
1OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀.
2Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.
3Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ.
4Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá.
5Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran?
6Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ?
7Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.
8Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.
9Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa.
10Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu.
11Otitọ yio rú jade lati ilẹ wá: ododo yio si bojuwò ilẹ lati ọrun wá.
12Nitõtọ Oluwa yio funni li eyi ti o dara; ilẹ wa yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá.
13Ododo yio ṣãju rẹ̀; yio si fi ipasẹ rẹ̀ ṣe ọ̀na.

Currently Selected:

O. Daf 85: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in