YouVersion Logo
Search Icon

O. Daf 8

8
Ògo OLUWA ati ipò eniyan
1OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye! iwọ ti o gbé ogo rẹ kà ori awọn ọrun.
2Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu ni iwọ ti ṣe ilana agbara, nitori awọn ọta rẹ, nitori ki iwọ ki o le mu ọta olugbẹsan nì dakẹjẹ.
3Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ.
4Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rẹ̀? ati ọmọ enia, ti iwọ fi mbẹ̀ ẹ wò.
5Iwọ sa da a li onirẹlẹ diẹ jù Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e li ade.
6Iwọ mu u jọba iṣẹ ọwọ rẹ; iwọ si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀;
7Awọn agutan ati awọn malu pẹlu, ati awọn ẹranko igbẹ;
8Awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati awọn ẹja okun, ti o nkọja lọ nipa ọ̀na okun.
9Oluwa, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyìn to ni gbogbo aiye!

Currently Selected:

O. Daf 8: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in